6 Dáfídì àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pẹ̀lú Rẹ̀ lọ sí Báláhì ti Júdà (Kiriati-Jéárímù) láti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run Olúwa tí a fi orúkọ Rẹ̀ pè, tí ó jókòó láàrin kérúbù-gòkè wá.
7 Wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run láti ilé Ábínádábù lórí kẹ̀kẹ́ túntún, Usà àti Áhíò ń sọ́ ọ.
8 Dáfídì àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni wọ́n ṣe àjọyọ̀ pẹ̀lú gbogbo agbára wọn níwájú Ọlọ́run, pẹ̀lú orin àti pẹ̀lú ohun èlò orin olóhùn gooro, písátérù, tíńbálì, síńbálì àti ìpè.
9 Nígbà tí wọ́n dé sí ilẹ̀ pakà ti Kídónì, Úsà na ọwọ́ Rẹ̀ síta láti di àpótì ẹ̀rí Olúwa mú, nítorí màlúù kọ̀ṣẹ̀.
10 Ìbínú Olúwa, sì ru sí Úsà, ó sì lùú bolẹ̀ nítorí o ti fi ọwọ́ Rẹ̀ lórí Àpótí ẹ̀rí. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì kú síbẹ̀ níwájú Ọlọ́run.
11 Nígbà náà Dáfídì sì bínú nítorí ìbínú Olúwa ké jáde lórí Úsá, àti títí di òní, wọ́n sì ń pe ibẹ̀ ní péresì-Ùsà.
12 Dáfídì sì bẹ̀rù Ọlọ́run ní ọjọ́ náà, ó sì bèèrè pé, Báwo ni èmi náà ó ṣe gbé àpótí ẹ̀rí Olórun sí ọ̀dọ̀ mi?