10 Ìyìn nínú orúkọ Rẹ̀ mímọ́;jẹ kí ọkàn àwọn tí ó yin Olúwa kí ó yọ̀.
11 Ẹ wá Olúwa àti agbára Rẹ̀;O wá ojú Rẹ̀ nígbà gbogbo.
12 Rántí àwọn ìyanu tí Ó ti ṣe,isẹ́ ìyanu Rẹ̀ àti ídájọ́ tí Ó ti sọ.
13 A! èyin ìran ọmọ Ísírẹ́lì ìránṣẹ́ Rẹ̀,àwon ọmọ Jákọ́bù, ẹ̀yin tí ó ti yàn.
14 Òun ni Olúwa Ọlọ́run wa;ìdájọ́ Rẹ̀ wà ní gbogbo ayé.
15 Ó ránti májẹ̀mú rẹ́ títí láé,ọ̀rọ̀ tí Ó pa láṣẹ fún ẹgbẹ̀rún ìran,
16 Májẹ̀mu tí ó dá pẹ̀lú Ábúráhámù,ìbúra tí ó ṣe pẹ̀lú fún Ísákì.