6 Àti Bénáià àti Jahaṣíélì àwọn àlùfáà ni yóò fọn ipè dédé níwájú àpótí ẹ̀rí méjẹ̀mú ti Ọlọ́run.
7 Ní ọjọ́ náà Dáfídì kọ́kọ́ fi lé Ásáfù àti àwon ẹlẹgbẹ́ Rẹ̀ lọ́wọ́ orin Dáfídì ti ọpẹ́ sí Olúwa:
8 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, ẹ pe orúkọ Rẹ̀,ẹ fi iṣẹ́ Rẹ̀ hàn nínú àwọn ènìyàn fún ohun tí ó ṣe
9 Ẹ kọrin síi, ẹ kọrin ìyìn, síi,Ẹ sọ ti gbogbo iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀
10 Ìyìn nínú orúkọ Rẹ̀ mímọ́;jẹ kí ọkàn àwọn tí ó yin Olúwa kí ó yọ̀.
11 Ẹ wá Olúwa àti agbára Rẹ̀;O wá ojú Rẹ̀ nígbà gbogbo.
12 Rántí àwọn ìyanu tí Ó ti ṣe,isẹ́ ìyanu Rẹ̀ àti ídájọ́ tí Ó ti sọ.