13 Èmi yóò jẹ́ bàbá Rẹ̀, Òun yóò sì jẹ́ ọmọ mi. Èmi kì yóò mú ìfẹ́ mi kurò lọ́dọ̀ Rẹ̀ láéláé gẹ́gẹ́ bí mo se mú un kúrò lọ́dọ̀ àwọn aṣáájú Rẹ̀.
14 Èmi yóò gbé e ka orí ilé mi àti ìjọba mi títí láé; ìtẹ́ Rẹ̀ ni a ó fi ìdí Rẹ̀ múlẹ̀ títí láé.’ ”
15 Nátanì ròyìn fún Dáfídì gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ ti Ìfihàn yí.
16 Nígbà náà, ọba Dáfídì wọlé lọ, ó sì jòkó níwájú Olúwa ó sì wí pé:“Ta ni èmi, Olúwa Ọlọ́run, àti ki ni ìdílé mi, tí ìwọ mú mi dé ibí?
17 Pẹ̀lú bí ẹni pé èyí kò tó lojú rẹ, Ọlọ́run. Ìwọ ti sọ̀rọ̀ nipa ọjọ́ iwáju ilé ìránṣẹ́ rẹ. Ìwọ ti wò mí bí ẹni pé èmi ni ẹni gbígbéga jù láàárin àwọn ọkùnrin Olúwa Ọlọ́run.
18 “Kí ni ohun tí Dáfídì tún lè sọ nítorí ọlá tí o bù fún ìránṣẹ́ rẹ? Nítorí tí ìwọ mọ ìransẹ́ rẹ,
19 Olúwa. Nítorí ti ìránṣẹ́ rẹ àti gẹ́gẹ́ bí àṣẹ rẹ, ìwọ ti ṣe ohun ńlá yìí àti láti fi gbogbo ìleri ńlá yìí hàn.