3 Élámù ẹlẹ́ẹ̀kaàrún,Jehóhánánì ẹlẹ́ẹ̀kẹfààti Eliéhóémáì ẹlẹ́ẹ̀keje.
4 Obedi-Édómù ni àwọn ọmọkùnrin pẹ̀lú:Ṣémáíà àkọ́bí,Jéhóṣábádì ẹlẹ́ẹ̀kejì,Jóà ẹlẹ́ẹ̀kẹta,Ṣákárì ẹlẹ́ẹ̀kẹrin,Nétanélì ẹlẹ́ẹ̀kaàrún,
5 Ámíélì ẹ̀kẹfà,Ísákárì ẹ̀kejeàti péúlétaì ẹ̀kẹjọ(Nítorí tí Ọlọ́run ti bùkún Óbédì Édómù).
6 Ọmọ Rẹ̀ Ṣémáíà ní àwọn ọmọkùnrin pẹ̀lú tí wọ́n jẹ́ olórí ní ìdílé bàbá a wọn nítorí wọ́n jẹ́ ọkùnrin tó lágbára.
7 Àwọn ọmọ Ṣémáíà: Ótínì, Refáélì, Óbédì àti Élíṣábádì; àwọn ìbátan Rẹ̀ Élíhù àti Sémákíà jẹ́ ọkùnrin alágbára
8 Gbogbo wọ̀nyí ní ìran ọmọ Obedi Édómù; àwọn àti ọmọkùnrin àti ìbátan wọn jẹ́ alágbára ọkùnrin pẹ̀lú ipá láti ṣe ìsìn náà. Àtẹ̀lé Obedi Édómù méjìlélọ́gọ́ta (62) ni gbogbo Rẹ̀.
9 Móésélémíà ní àwọn ọmọ àti àwọn ìbátan, tí ó jẹ́ alágbára méjìdínlógún (18) ni gbogbo wọn.