1 Dáfídì pe gbogbo àwọn oniṣẹ́ ti Ísírẹ́lì láti pẹ́jọ ní Jérúsálẹ́mù: Àwọn ìjòyè lórí àwọn ẹ̀yà, àwọn alákòóṣo ìpín nínú iṣẹ́ bí ọba, àwọn alákòóṣo ẹgbẹgbẹ̀rún àti àwọn alákòóṣo ọrọrún àti àwọn onísẹ́ tí ó wà ní ìdí bíbojútó gbogbo àwọn ẹrù àti ohun ọ̀sìn tí ó jẹ́ ti ọba àti àwọn ọmọ Rẹ̀ pẹ̀lú ààfin àwọn onísẹ́ ààfin, àwọn ọkùnrin alágbára àti gbogbo àwọn ògbójú jagunjagun lápapọ̀.
2 Ọba Dáfídì dìde dúró ní ẹṣẹ̀ Rẹ̀, o sì wí pé Fetísílẹ̀ sí mi, ẹyin ará mi àti ẹ̀yin ènìyàn mi. Èmi ní o ni ọkàn mi láti kọ́ ilé gẹ́gẹ́ bí ibi ìsinmi fún àpótí ẹ̀rí májẹ̀mú tí Olúwa fún àpótí ìtìsẹ̀ Ọlọ́run wa, èmi sì gbèrò láti kọ́ ọ.
3 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run sọ fún mi pé: Ìwọ kò gbodò kọ́ ilé fún orúkọ mi, nítorí ìwọ jẹ́ jagunjagun, ìwọ sì ti tàjẹ̀sílẹ̀.
4 “Síbẹ̀ Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì yàn mí láti gbogbo ìdílé láti jẹ́ ọba lórí Ísírẹ́lì, títí láé. Ó yan Júdà gẹ́gẹ́ bí olórí, àti láti ilé Júdà, ó yan ìdílé mi, àti láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ baba à mí, ó tẹ́ Ẹ lọ́rùn láti fi mí ṣe ọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì.