2 Réáíà ọmọ Ṣóbálì ni baba Jáhátì, àti Jáhátì baba Áhúmáyì àti Láhádì. Àwọn wọ̀nyí ni ẹ̀yà ará Ṣórà.
3 Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Étanílù:Jésírélì, Ísímà, Ídíbásì, orúkọ arábìnrin wọn sì ni Sélélípónì
4 Pénúélì sì ni baba Gédórì, àti Édérì baba Húṣà.Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Húrì, Àkọ́bí Éfúrátà àti baba Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.
5 Áṣárì bàbá Jékóà sì ní aya méjì, Hélà àti Nárà.
6 Nárà sì bí Áhúsámù, Héférì Téménì àti Háhásítarì. Àwọn wọ̀nyí sì ni àwọn ọmọ Nátà.
7 Àwọn ọmọ Hélà:Ṣérétì Ṣóárì, Étanì,
8 Àti kósì ẹnítí ó jẹ́ baba Ánúbì àti Hásóbébà àti ti àwọn Ẹ̀yà Áháríhélì ọmọ Hárúmù.