62 Àwọn ìran ọmọ Géríṣómù, sí ìdílé ni a pín ìlú mẹ́talá fún láti ẹ̀yà àwọn ẹ̀yà Íṣákárì, Áṣérì àti Náfítalì, àti láti apá ẹ̀yà Mánásè tí ó wà ní Básánì.
63 Àwọn ìran ọmọ Mérárì, ìdílé sí ìdílé, ní a pín ìlú méjìlá fún láti ẹ̀yà Rúbẹ́nì, Gádì àti Ṣébúlúní.
64 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fún àwọn ará Léfì ní ìlú wọ̀nyí pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.
65 Láti ẹ̀yà Júdà, Síméónì àti Bẹ́ńjámínì ni a pín ìlú tí a ti dárúkọ wọn sẹ́yìn fún.
66 Lára àwọn ìdílé Kóhátì ni a fún ní ìlú láti ẹ̀yà Éfúráímù gẹ́gẹ́ bí ìlú agbégbé wọn.
67 Ní òkè orílẹ̀ èdè Éfíráímù, a fún wọn ní Ṣékémù (Ìlú ńlá ti ààbò), àti Géṣérì
68 Jókíméámù, Bétì-Hórónì.