74 Láti ẹ̀yà Áṣérìwọ́n gba Máṣálì Ábídónì,
75 Húkokì àti Réhóbù lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn;
76 Pẹ̀lú láti ẹ̀yà Náfítalìwọ́n gba Kédésì ní Gálílì, Hámoníà Kíríátaímù, lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.
77 Àwọn ará Mérárì (ìyókù àwọn ará Léfì) gbà nǹkan wọ̀nyí:Láti ẹ̀yà Sébúlúnìwọ́n gba Jókíneámù, Kárítahì, Rímónò àti Tábórì, lápapọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù wọn;
78 Láti ẹ̀yà Rúbẹ́nì rékọjá Jódánì ìlà oòrùn Jẹ́ríkòwọ́n gba Bésérì nínú ihà Jáhíṣáhì,
79 Kédémótì àti Méfátù, lápapọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko, tútù wọn;
80 Pẹ̀lú láti ẹ̀yà Gádìwọ́n gba Rámóà ní Gílíádì Máhánáímù,