1 Nígbà tí Réhóbóámù dé Jérúsálẹ́mù, ó kó ilé Júdà àti Bẹ́ńjámínì jọ, ọ̀kẹ́ mẹ́sàn án ènìyàn tí a yàn, tí wọ́n jẹ́ ológun, láti bá Ísírẹ́lì jà kí ó lè mú ìjọba naà padà bọ̀ sọ́dọ̀ Réhóbóámù.
2 Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yí wá sí ọ̀dọ̀ Ṣémáíà ènìyàn Ọlọ́run:
3 “Wí fún Rehóbóámù ọmọ Sólómónì ọba Júdà, sí gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Júdà àti Bẹ́ńjámínì,
4 ‘Èyí ní ohun tí Olúwa wí. Ẹ má ṣe gòkè lọ lati lọ jà pẹ̀lú arákùnrin yín, ẹ lọ sílé, gbogbo yín, nítorí ti ìṣe mi nìyí.’ ” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tẹ̀lé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n sì padà sẹ́yìn láti yan lọ dojúkọ Jéróbóámù.
5 Réhóbóámù ń gbe ní Jérúsálẹ́mù ó sì kọ́ àwọn ìlú fún ààbò ní Júdà.