2 Kíróníkà 25:1-7 BMY

1 Ámásíà jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba, ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (29) Orúkọ ìyá rẹ̀ a máa jẹ́ Jéhóadánì, ó wá láti Jérúsálẹ́mù.

2 Ó ṣe ohun tí ó dára lójú Olúwa, ṣùgbọ́n kì í ṣe tọkàntọkàn.

3 Lẹ́yìn tí ìjọba ti wà ní ìdarí rẹ̀, ó pa àwọn onísẹ́ tí ó pa baba rẹ̀ ọba.

4 Síbẹ̀ kò pa àwọn ọmọ wọn, ṣùgbọ́n ó ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a kọ nínú òfin nínú ìwé Mósè, níbi tí Olúwa ti paláṣẹ pé: “A kò gbọdọ̀ pa àwọn baba fún àwọn ọmọ wọn tàbí àwọn ọmọ fún baba wọn; Olúkúlùkù ni kí ó kú fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.”

5 Ámásíà, pe gbogbo àwọn ènìyàn Júdà pọ̀, ó sì fi iṣẹ́ lé wọn lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn sí àwọn alákòóso ẹgbẹgbẹ̀rún àti àwọn alákòóso ọrọrún fún gbogbo Júdà àti Bẹńjámínì, ó sì gbá iye wọn láti ẹni ogún ọdún àti jù bẹ́ẹ̀ lọ jọ, ó sì ríi pé ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀dógún (300,000) àwọn ọkùnrin ni ó ti múra fún ìsìn ogun, tí ó lè gbá ọ̀kọ̀ àti àpáta mú.

6 Ó sì yá (100,000) ọ̀kẹ́ márùn-ún àwọn ọkùnrin oníjà láti Ísírẹ́lì fún ọgọ́rùn-ún mẹ́wàá àwọn talẹ́ntì fàdákà.

7 Ṣùgbọ́n ènìyàn Ọlọ́run kan tọ̀ ọ́ wá ó sì wí pé, “Ọba, àwọn ọ̀wọ́-ogun láti Ísírẹ́lì kò gbọdọ̀ yan pẹ̀lú rẹ, nítorí tí Olúwa kò wà pẹ̀lú Ísírẹ́lì kì í ṣe pẹ̀lú ẹnìkankan láti Éfíráímù.