23 Ó sì rú ẹbọ sí òrìṣà àwọn Dámásíkù, ẹni tí ó sẹ́gun wọn, nítorí ó rò wí pé, “Nítorí àwọn òrìṣà àwọn síríà ti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọn kí ó bà lè ràn mí lọ́wọ́.” Ṣùgbọ́n àwọn ni ìparun rẹ̀ àti ti gbogbo Ísírẹ́lì.
24 Áhásì sì kó jọ gbogbo ohun èlò lati ilé Olúwa jọ ó sì kó wọn lọ. Ó sì ti ilẹ̀kùn ilé Olúwa ó sì tẹ́ pẹpẹ fún ara rẹ̀ ní gbogbo igun Jérúsálẹ́mù.
25 Ní gbogbo ìlú Júdà ó sì kọ́ ibi gíga láti sun ẹbọ fún àwọn Ọlọ́run mìíràn. Kí ó sì mú Olúwa, Ọlọ́run àwọn Baba wọn bínú.
26 Ìyòókù iṣẹ́ ìjọba rẹ̀ àti gbogbo ọ̀nà rẹ̀, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, ni a kọ sínú ìwé àwọn ọba Júdà àti ti Ísírẹ́lì.
27 Áhásì sì sùn pẹ̀lú àwọn Baba rẹ̀ a sì sin ín ní ìlú Jérúsálẹ́mù ṣùgbọ́n wọn kò mú un wá sínú àwọn ìsà òkú àwọn ọba Ísírẹ́lì. Heṣekáyà ọmọ rẹ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.