2 Kíróníkà 32:1-7 BMY

1 Lẹ́yìn gbogbo èyí ti Heṣekíà ti fi otítọ́ se, Senakéríbù ọba Ásíríà wá ó sì gbógun ti Júdà. Ó gbógun ti àwọn ìlú ààbò, ó ń ronú láti ṣẹ́gun wọn fún ararẹ̀.

2 Nígbà tí Heṣekáyà rí i pé Senakérébù ti wá, àti pé ó fẹ́ láti dá ogun sílẹ̀ lóri Jérúsálẹ́mù,

3 Ó gbèrò pẹ̀lu àwọn ìjòyè rẹ̀ àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ tí wọ́n fẹ́rẹ̀ ẹ́ di orísun omi ní ìta ìlú ńlá, wọ́n sì ràn án lọ́wọ́.

4 Ọ̀pọ̀ ogun ọkùnrin péjọ, wọ́n sì dí gbogbo àwọn orísun àti àwọn omi tó ń ṣàn tí ó ń sàn gba ti ilẹ̀ naà. “Kí ni ó dé tí àwọn ọba Ásíríà fi wá tí wọ́n sì rí ọ̀pọ̀ omi?” Wọ́n wí.

5 Nígbà náà ó ṣiṣẹ́ gidigidi ní títún gbogbo ìtorí ara ògiri tí ó ti bàjẹ́ ṣe, ó sì ń kọ́ àwọn ilé iṣẹ́ gíga sókè rẹ̀. Ó kọ́ ògiri mìíràn sí ìta ìyẹn. Ó sì rán ibi ìfẹ̀yìntì lọ́wọ́ pẹ̀lú ibi ìtẹ́jú ilé níti ìlú ńlá Dáfídì. Ó ṣe ọ̀pọ̀ iye ohun ìjà àti àwọn àpáta.

6 Ó yan àwọn ìjòyè ológun sórí àwọn ènìyàn, ó sì pèwọ́n jọ, níwájú rẹ̀ ní ìbámu ní ìlú ńlá ti Dáfídì. Ó sì ki wọ́n láyà pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí:

7 “Ẹ jẹ́ alágbára, àti kí ẹ sì ní ìgboyà. Ẹ má se bẹ̀rù tàbí ní ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn nítorí tí ọba Ásíríà àti ọ̀pọ̀ ọmọ-ogun pẹ̀lú rẹ̀, nítorí tí agbára ńlá wà pẹ̀lú wa ju òun lọ.