2 Kíróníkà 32:8-14 BMY

8 Agbára ẹran ara nìkan ni ó wà pẹ̀lú rẹ̀ ṣùgbọ́n, pẹ̀lú wa ni Ọlọ́run láti ràn wá lọ́wọ́ àti láti ja ìjà wa.” Àwọn ènìyàn sì ní ìgboyà láti ara ohun tí Hesekía ọba Júdà wí.

9 Lẹ́yìn ìgbà tí Senakéríbù ọba Ásíríà àti gbogbo àwọn ogun rẹ̀ ń gbógun sí Lákíṣì. Ó rán àwọn ìjòyè rẹ̀ sí Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú iṣẹ́ yí fún Heṣekáyà ọba Júdà àti fún gbogbo àwọn ènìyàn Júdà tí ó wà níbẹ̀:

10 “Èyí ni ohun tí Senakéríbù ọba Ásíríà wí: Lórí kí ni ẹ̀yin gbé ìgbẹ́kẹ̀lé yín lé, tí ẹ̀yin fi dúró sí Jérúsálẹ́mù lábẹ́ ìgbógun sí?

11 Nígbà tí Heṣekáyà wí pé ‘Olúwa Ọlọ́run wa yóò gbà wá kúrò lọ́wọ́ ọba Ásíríà, ó ń sì yín tọ́ sọ́nà, kí ẹ bá lè kú fún ebi àti òǹgbẹ.’

12 Ṣé Heṣekáyà fún ra rẹ̀ kò mú àwọn ọlọ́run ibi gíga àti àwọn pẹpẹ kúrò, tí ó ń wí fún Júdà àti Jérúsálẹ́mù pé ‘Ẹ̀yin gbọdọ̀ sìn níwájú pẹpẹ kan àti láti sun àwọn ẹbọ lóri rẹ̀’?

13 “Ṣé ẹ̀yin kò mọ̀ ohun tí èmi àti àwọn bàbá mi ti ṣe sí gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ mìíràn? Ǹjẹ́ àwọn Ọlọ́run tí àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn ní agbára láti gba ilẹ̀ wọn kúrò lọ́wọ́ mi?

14 Ta ni nínú gbogbo àwọn òrìṣà orílẹ̀ èdè wọ̀nyí tí àwọn baba mi ti parun, tí ó le gbà ènìyàn rẹ̀ lọ́wọ́ mi, tí Ọlọ́run yín yóò fi le gbà yín lọ́wọ́ mi?