2 Ọba 1:12-18 BMY

12 “Tí Èmi bá jẹ́ ènìyàn Ọlọ́run,” Èlíjà sì dáhùn, “Ǹjẹ́ kí iná kí ó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run kí ó sì jó ọ run àti àwọn àádọ́ta ènìyàn rẹ!” Nígbà náà iná Ọlọ́run sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run ó sì jó o run pẹ̀lú àwọn àádọ́ta ènìyàn rẹ̀.

13 Bẹ́ẹ̀ ni ọba tún rán balógun kẹta pẹ̀lú àwọn àádọ́ta ọkùnrin. Balógun ẹ̀ẹ̀kẹ́ta lọ sí òkè, ó sì kúnlẹ̀ lórí orókún rẹ̀ níwájú Èlíjà. “Ènìyàn Ọlọ́run,” Ó sì bẹ̀bẹ̀ pé, “Ìwọ ènìyàn Ọlọ́run, jọ̀wọ́ jẹ́ kí ẹ̀mí mi àti ẹ̀mí àwọn àádọ́ta ìránṣẹ́ rẹ wọ̀nyí ṣọ̀wọ́n ní ojú rẹ!

14 Wò ó, iná ti sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run láti jó àwọn balógun méjì àràádọ́ta àkọ́kọ́ pẹ̀lú àràádọ́ta wọn. Ṣùgbọ́n Nísinsìn yìí ní ojúrere fún ẹ̀mí mi!”

15 Ańgẹ́lì Olúwa sọ fún Èlíjà pé, “Ṣọ̀kalẹ̀ lọ pẹ̀lú rẹ̀; má ṣe bẹ̀rù rẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni Èlíjà dìde ó sì ṣọ̀kalẹ̀ lọ pẹ̀lú rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ ọba.

16 Ó sọ fún ọba pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Ṣé nítorí wí pé kò sí Ọlọ́run ní Ísírẹ́lì fún ọ láti pè ni ìwọ fi rán ìránṣẹ́ lọ sí ọ̀dọ̀ Bálísébúbù, òrìṣà Ékírónì láti lọ ṣe ìwádìí? Nítorí pé o ṣe èyí, ìwọ kò níi dìde lórí ibùsùn tí o dúbúlẹ̀ lé láìsí àní àní ìwọ yóò kú!”

17 Bẹ́ẹ̀ ó sì kú, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa tí Èlíjà ti sọ.Nítorí Áhásáyà kò ní ọmọ, Jéhórámù jẹ ọba ní ọdún kejì tí Jéhórámù ọmọ Jèhósáfátì ọba Júdà.

18 Àti ní ti gbogbo àwọn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nígbà ìjọba Áhásáyà, àti ohun tí ó ṣe, ṣe a kò ha kọ wọ́n sí inú ìwé ọdọọdún ti àwọn ọba Ísírẹ́lì?