2 Ọba 10:10-16 BMY

10 Nígbà yìí, kò sí ọ̀rọ̀ kan tí Olúwa ti sọ sí ilé Áhábù tí yóò kùnà. Olúwa ti ṣe ohun tí ó ṣèlérí nípaṣẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ Èlíjà.”

11 Bẹ́ẹ̀ ni Jéhù pa gbogbo ẹni tí ó kù ní ilé Áhábù, pẹ̀lú pẹ̀lú gbogbo àwọn ọkùnrin ìjòyè rẹ̀, àwọn ọ̀rẹ́ ẹ rẹ̀ tímọ́-tímọ́ àti àwọn àlùfáà rẹ̀, láì ku ẹni tí ó yọ nínú ewu fún un.

12 Jéhù jáde lọ, ó sì lọ sí ọ̀kánkán Ṣamáríà. Ní Bẹti-Ékédì tí àwọn olùṣọ́ àgùntàn.

13 Ó pàdé díẹ̀ lára àwọn ìbátan Áhásáyà ọba Júdà, ó sì béèrè, “Ta ni ẹ̀yin ń ṣe?”Wọ́n wí pé, “Àwa jẹ́ ìbátan Áhásáyà, àwa sì ti wá láti kí ìdílé ọba àti ti mọ̀mọ́ ayaba.”

14 “Mú wọn láàyè!” ó pàṣẹ. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n mú wọn láàyè, wọ́n sì pa wọ́n ní ẹ̀bá kọ̀nga Bẹti-Ékédì, ọkùnrin méjìlélógójì. Kò sì fi ẹnìkan sílẹ̀ láìkù.

15 Lẹ́yìn ìgbà tí ó kúrò níbẹ̀, ó wá sórí Jéhónádábù ọmọ Rékábù tí ó wà ní ọ̀nà rẹ̀ láti lọ bá a. Jéhù kí i, ó sì wí pé, “Ṣé ìwọ wà ní ìbárẹ́ pẹ̀lú mi, bí èmi ti wa pẹ̀lú ù rẹ?”“Èmi wà,” Jéhónádábù dáhùn.“Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀,” Jéhù wí, “fún mi ní ọwọ́ ọ̀ rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe pẹ̀lú, Jéhù sì ràn án ọ́ lọ́wọ́ sókè sí inú kẹ̀kẹ́.

16 Jéhù wí pé, “Wá pẹ̀lú ù mi; kí o sì rí ìtara mi fún Olúwa.” Nígbà náà ó jẹ́ kí ó gun kẹ̀kẹ́ rẹ̀.