2 Ọba 10:17-23 BMY

17 Nígbà tí Jéhù wá sí Ṣamáríà, ó pa gbogbo àwọn tí a fi kalẹ̀ ní ìdílé Áhábù; ó pa wọ́n run, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa tí a sọ sí Èlíjà.

18 Nígbà náà, Jéhù kó gbogbo àwọn ènìyàn jọ, ó sì wí fún wọn pé, “Áhábù sin Báálì díẹ̀; ṣùgbọ́n Jéhù yóò sìn ín púpọ̀.

19 Nísinsìn yìí, ẹ pe gbogbo àwọn wòlíì Báálì jọ, gbogbo àwọn òjíṣẹ́ rẹ̀ àti gbogbo àlùfáà rẹ̀. Rí i wí pé, kò sí nǹkankan tí ó ń sọnù nítorí ẹ̀mi yóò rú ẹbọ ńlá fún Báálì. Ẹnìkíní tí ó bá kọ̀ láti wá, kò ní wà láàyè mọ́.” Ṣùgbọ́n Jéhù fi ẹ̀tàn ṣe é, kí ó lè pa àwọn òjíṣẹ́ Báálì run.

20 Jéhù wí pé, “ẹ pe àpẹ̀jọ ní wòyí ọ̀la fún Báálì.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kéde rẹ.

21 Nígbà náà, ó rán ọ̀rọ̀ káàkiri Ísírẹ́lì, gbogbo àwọn òjíṣẹ́ Báálì sì wá: kò sí ẹnìkan tí ó dúró lẹ́yìn. Wọ́n kún ilé tí a kọ́ fún òrìṣà títí tí ó fi kún láti ìkángun èkíní títí dé èkejì.

22 Jéhù sì sọ fún olùṣọ́ pé, “Kí ó mú aṣọ ìgúnwà wá fún gbogbo àwọn òjíṣẹ́ Báálì.” Bẹ́ẹ̀ ni ó mú aṣọ ìgúnwà jáde wá fún wọn.

23 Nígbà náà, Jéhù àti Jéhónádábù ọmọ Rékábù lọ sí inú ilé tí a kọ́ fún òrìṣà Báálì. Jéhù sì wí fún àwọn òjíṣẹ́ Báálì pé, “Wò ó yíká, kí o sì rí i pé kò sí ìránṣẹ́ Ọlọ́run kankan pẹ̀lú yín níbí—kìkì òjíṣẹ́ Báálì.”