2 Ọba 10:24-30 BMY

24 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n wọ inú ilé lọ láti lọ rú ẹbọ àti ọrẹ sísun. Nísinsìn yìí Jéhù ti rán ọgọ́rin ọkùnrin sí ìta pẹ̀lú ìkìlọ̀ yìí: “Tí ẹnikẹ́ni nínú yín bá jẹ́ kí ẹnikẹ́ni nínú àwọn ọkùnrin tí mo ń gbé sí ọwọ́ yín ó sá lọ, yóò jẹ́ ẹ̀mí yín fún ẹ̀mí ì rẹ.”

25 Ní kété tí Jéhù ti parí ṣíṣe ọrẹ sísun, ó pàṣẹ fún àwọn olùṣọ́ àti àwọn ìjòyè: “Wọlé lọ, kí o sì pa wọ́n; Má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni kí ó sálọ.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gé wọn lulẹ̀ pẹ̀lú idà. Àwọn olùṣọ́ àti ìjòyè ju ara wọn síta, wọ́n sì wọ inú ojúbọ ti ilé tí a kọ́ fún òrìṣà Báálì.

26 Wọ́n gbé òkúta bíbọ náà jáde láti inú ilé tí a kọ́ fún òrìṣà Báálì, wọ́n sì jó o.

27 Wọ́n fọ́ òkúta bíbọ ti Báálì náà túútúú, wọ́n sì ya ilé òrìṣà Báálì bolẹ̀. Àwọn ènìyàn sì ń lò ó fún ilé ìgbẹ́ títí di ọjọ́ òní.

28 Bẹ́ẹ̀ ni Jéhù pa sísin Báálì run ní Ísírẹ́lì.

29 Bí ó ti wù kí ó rí, kò yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jéróbóámù ọmọ Nébátì, tí ó ṣokùnfà Ísírẹ́lì láti dá—ti sísin ẹgbọ̀rọ̀ màlúù wúrà ní Bétélì àti Dánì.

30 Olúwa sì sọ fún Jéhù pé, “Nítorí ìwọ ti ṣe dáradára ní ṣíṣe èyí tí ó tọ́ ní ojú mi, tí o sì ti ṣe sí ilé Áhábù gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí ó wà ní ọkàn mi, àwọn ọmọ ọ̀ rẹ yóò jókòó lórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì títí dé ìran kẹrin.”