2 Ọba 2:6-12 BMY

6 Nígbà náà Èlíjà wí fún un pé, “Dúró níbí; Olúwa rán mi lọ sí Jọ́dánì.”Ó sì dá a lóhùn pé, “Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ wí pé, Olúwa yè àti gẹ́gẹ́ bí o ti yè, èmi kò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn méjèèjì sì jọ ń lọ.

7 Àádọ́ta àwọn ọkùnrin ọmọ wòlíì sì lọ láti lọ dúró ní ọ̀nà jínjìn, wọ́n sì kọ ojú da ibi tí Èlíjà àti Èlíṣà ti dúró ní Jọ́dánì.

8 Èlíjà sì mú agbádá ó sì ká a sókè ó sì lu omi náà pẹ̀lú rẹ̀. Omi náà sì pín sí ọ̀tún àti sí òsì, àwọn méjèèjì sì rékọjá lórí ilẹ̀ gbígbẹ̀.

9 Nígbà tí wọ́n rékọjá, Èlíjà sì wí fún Èlíṣà pé, “Sọ fún mi, kí ni èmi lè ṣe fún ọ kí ó tó di wí pé wọ́n gbà mí kúrò lọ́dọ̀ rẹ?”“Jẹ́ kí èmi kí ó jogún ìlọ́po méjì ẹ̀mí rẹ.” Ó dá a lóhùn.

10 “Ìwọ ti béèrè ohun tí ó ṣòro,” Èlíjà wí pé, “Síbẹ̀ tí ìwọ bá rí mi nígbà tí a bá gbà mí kúrò lọ́wọ́ rẹ, yóò jẹ́ tìrẹ bí bẹ́ẹ̀ kọ́ kò ní rí bẹ́ẹ̀.”

11 Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ń rìn lọ tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ pọ̀, lọ́gán kẹ̀kẹ́ iná àti ẹsin iná yọ sí wọn ó sì ya àwọn méjèèjì nípa, Èlíjà sì gòkè lọ sí ọ̀run pẹ̀lú àjà.

12 Èlíṣà rí èyí ó sì kígbe sókè, “Baba mi! Baba mi! Kẹ̀kẹ́ àti ẹlẹ́ṣin Ísírẹ́lì!” Èlíṣà kò sì rí i mọ́. Ó sì mú aṣọ ara rẹ̀ ó sì fà wọ́n ya sọ́tọ̀.