2 Ó sì ṣe èyí tí ó dára lójú Olúwa, ó sì rìn ní ọ̀nà Dáfídì bàbá a rẹ̀, kò sì yípadà sí apá ọ̀tún tàbí sí apá òsì.
3 Ní ọdún kejìdínlógún tí ó fi jọba. Ọba Jòsáyà rán akọ̀wé, Ṣáfánì ọmọ Ásálíà, ọmọ Mésúlámù, sí ilé Olúwa. Ó wí pé;
4 “Gòkè lọ sí ọ̀dọ̀ Hílíkíyà olórí àlùfáà, kí o sì jẹ́ kí ó sírò iye owó tí a mú wá sí ilé Olúwa, tí àwọn olùṣọ́nà ti gbà lọ́wọ́ àwọn ènìyàn.
5 Ẹ sì jẹ́ kí wọn ó fi lé àwọn ọkùnrin tí a ti yàn láti bojútó iṣẹ́ náà lórí ilé Olúwa. Kí ẹ sì jẹ́ kí àwọn ọkùnrin san án fún àwọn òṣìṣẹ́ tí ó ń tún ilé Olúwa ṣe.
6 Àwọn gbẹ́nà-gbẹ́nà, àwọn ọ̀mọ̀lé àti àwọn akọ́lé. Bákan náà ni wọ́n ra igi àti òkúta ọlọ́ṣọ̀ọ́ láti fi tún tẹ́ḿpìlì ṣe.
7 Ṣùgbọ́n wọn kò ní láti ṣe ìṣirò fún owó náà tí a fi fún wọn, nítorí wọ́n ṣe òtítọ́.”
8 Hílíkíyà olórí àlùfáà sọ fún Ṣáfánì akọ̀wé pé, “Èmi rí ìwé òfin nílé Olúwa.” Ó fi fún Ṣáfánì, ẹni tí ó kà á.