12 “Kò sí ọ̀kan nínú wa, Olúwa ọba mi,” ọ̀kan lára ìránṣẹ́ rẹ̀ sì wí pé, “ṣùgbọ́n Èlíṣà, wòlíì tí ó wà ní Ísírẹ́lì, sọ fún ọba Ísírẹ́lì ọ̀rọ̀ gangan tí ó sọ nínú yàrá rẹ̀.
13 “Lọ, kí ẹ lọ wo ibi tí ó wà,” ọba pa á láṣẹ, “Kí èmi kí ó lè rán ènìyàn láti lọ mú un wá.” Ìròyìn padà wá. “Ó wà ní Dótanì.”
14 Nígbà náà ó rán àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ àti ogun ńlá tí ó le síbẹ̀. Wọ́n sì lọ ní alẹ́ wọ́n sì yí ìlú náà ká.
15 Nígbà tí ìránṣẹ́ ènìyàn Ọlọ́run dìde ó sì jáde lọ ní òwúrọ̀ kùtùkùtù ọjọ́ kejì, ogun pẹ̀lú ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ wọn ti yí ìlú náà ká. “Yé è, Olúwa mi, kí ni kí àwa kí ó ṣe?” ìránṣẹ́ náà béèrè.
16 “Má ṣe bẹ̀rù,” wòlíì náà dáhùn, “Àwọn tí ó wà pẹ̀lú wa, wọ́n pọ̀ ju àwọn tí ó wà pẹ̀lú wọn lọ.”
17 Èlíṣà sì gbàdúrà, “Olúwa, la ojú rẹ̀ kí ó ba à lè ríran.” Nígbà náà Olúwa la ojú ìránṣẹ́ náà, ó sì wò, ó sì rí òkè ńlá tí ó kún fún ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ iná gbogbo yí Èlíṣà ká.
18 Bí àwọn ọ̀tá ṣe ń sọ̀kalẹ̀ wá níwájú rẹ, Èlíṣà gbàdúrà sí Olúwa pé. “Bu ìfọ́jú lu àwọn ènìyàn wọ̀nyí,” Olúwa sì se gẹ́gẹ́ bí Èlíṣà ti béèrè.