2 Ọba 6:18-24 BMY

18 Bí àwọn ọ̀tá ṣe ń sọ̀kalẹ̀ wá níwájú rẹ, Èlíṣà gbàdúrà sí Olúwa pé. “Bu ìfọ́jú lu àwọn ènìyàn wọ̀nyí,” Olúwa sì se gẹ́gẹ́ bí Èlíṣà ti béèrè.

19 Èlíṣà sọ fún wọn pé “Èyí kì í ṣe ọ̀nà bẹ́ẹ̀ ni èyí kì í ṣe ìlú náà. Tẹ̀lé mi, èmi yóò mú u yín lọ sí ọ̀dọ̀ ọkùnrin tí ẹ̀yin ń wá.” Ó sì sìn wọ́n lọ sí Samáríà.

20 Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n wọ ìlú náà, Èlíṣà wí pé, “Olúwa, la ojú àwọn ọkùnrin wọ̀nyí kí wọn kí ó lè ríran.” Nígbà náà Olúwa la ojú wọn, wọ́n sì ríran, wọ́n sì wà níbẹ̀, nínú Samáríà.

21 Nígbà tí ọba Ísírẹ́lì rí wọn, ó béèrè lọ́wọ́ Èlíṣà pé, “Ṣé kí èmi kí ó pa wọ́n, Baba mi? Ṣé kí èmi kí ó pa wọ́n?”

22 “Má se pa wọ́n,” ó dáhùn. “Ṣé ìwọ yóò pa àwọn ọkùnrin tí ìwọ mú pẹ̀lú idà rẹ tàbí ọrun rẹ? Gbé oúnjẹ àti omi ṣíwájú wọn kí wọn kí ó lè jẹ kí wọn sì mu, nígbà náà kí wọn padà lọ sí ọ̀dọ̀ ọ̀gá wọn.”

23 Bẹ́ẹ̀ ni ó pèṣè àṣè ńlá fún wọn, lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jẹ tí wọ́n mu, ó sì rán wọn lọ, wọ́n sì padà sí ọ̀dọ̀ ọ̀gá wọn. Bẹ́ẹ̀ ni ẹgbẹ́ láti Árámù dáwọ́ ìgbógun ti ilẹ̀ Ísírẹ́lì dúró.

24 Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, ni Bẹni-Hádádì ọba Árámù kó gbogbo àwọn ogun rẹ̀ jọ wọ́n sì yan sókè wọ́n sì dúró ti Samáríà.