16 Ní ọdún karùn-ún ti Jórámù ọmọ Áhábù ọba Ísírẹ́lì, nígbà tí Jéhóṣáfátì jẹ́ ọba Júdà, Jéhórámù ọmọ Jéhóṣáfátì bẹ̀rẹ̀ ìjọba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba Júdà.
17 Ó jẹ́ ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba. Ó sì jẹ ọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mẹ́jọ.
18 Ó sì rìn ní ọ̀nà ọba Ísírẹ́lì, gẹ́gẹ́ bí ilé Áhábù ti lọ, nítorí ó fẹ́ ọmọbìnrin Áhábù ó sì ṣe ohun búburú níwájú Olúwa.
19 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, nítorí ti ìránṣẹ́ rẹ̀ Dáfídì. Olúwa kò fẹ́ pa Júdà run, ó ti ṣèlérí láti ṣètọ́jú ìmọ́lẹ́ fún Dáfídì àti àwọn ilé rẹ̀ títí láéláé.
20 Ní àsìkò Jéhórámù, Édómù ṣọ̀tẹ̀ lórí Júdà, ó sì jẹ́ ọba fúnrararẹ̀.
21 Bẹ́ẹ̀ ni Jéhórámù lọ sí Ṣáírì pẹ̀lú gbogbo kẹ̀kẹ́ rẹ̀. Àwọn ará Édómù sì yí i ká àti kẹ̀kẹ́ àwọn olórí wọn, ṣùgbọ́n ó dìde dúró ní òru; àwọn ogun rẹ̀ síbẹ̀ síbẹ̀, sá padà lọlé.
22 Títí ó fi di òní, Édómù wà nínú ọ̀tẹ̀ lórí Júdà, Líbinà ṣọ̀tẹ̀ ní àkókò kan náà.