20 Dáfídì sì dìde ní ilẹ̀, ó sì wẹ̀, ó fi òróró pa ara, ó sì pààrọ̀ aṣọ rẹ̀, ó sì wọ inú ilé Olúwa lọ, ó sì wólẹ̀ sin: ó sì wá sí ilé rẹ̀ ó sì bèèrè, wọ́n sì gbé òunjẹ kalẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì jẹun.
21 Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì bí léèrè pé, “Kí lèyí tí ìwọ ṣe yìí? Nítorí ọmọ náà nígbà tí ó ń bẹ láàyè ìwọ gbààwẹ̀, o sì sunkún; ṣùgbọ́n nígbà tí ọmọ náà kú, ó dìde ó sì jẹun.”
22 Ó sì wí pé, “Nígbà tí ọmọ náà ń bẹ láàyè, èmi gbààwẹ̀, èmi sì sunkún: nítorí tí Èmi wí pé, ‘Ta ni ó mọ̀ bí Ọlọ́run ó ṣàánú mi, kí ọmọ náà le yè.’
23 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ó ti kú, nítorí kín ni èmi ó ṣe máa gbààwẹ̀? Èmi ha tún lè mú-un padà bí? Èmi ni yóò tọ̀ ọ́ lọ, òun kì yóò sì tún tọ̀ mí wá.”
24 Dáfídì sì ṣìpẹ̀ fún Bátíṣébà aya rẹ̀, ó sì wọlé tọ̀ ọ́, ó sì bá a dàpọ̀: òun sì bí ọmọkùnrin kan, Dáfídì sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Sólómónì: Olúwa sì fẹ́ ẹ.
25 Ó sì rán Nátanì wòlíì, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jédídíáyà, nítorí Olúwa.
26 Jóábù sì bá Rábà ti àwọn ọmọ Ámónì jagun, ó sì gba ìlú ọba wọn.