2 Sámúẹ́lì 17:11-17 BMY

11 “Nítorí náà èmi dámọ̀ràn pé: Kí gbogbo Ísírẹ́lì wọ́jọ pọ̀ sọ́dọ̀ rẹ, láti Dánì títí dé Bééríṣébà, gẹ́gẹ́ bí iyanrìn létí òkun fún ọ̀pọ̀lọpọ̀; àti pé, kí ìwọ tìkárarẹ ó lọ sí ogun náà.

12 Àwá ó sì yọ sí i níbikíbi tí àwa o gbé rí i, àwa ó sì yí i ká bí ìrì ti ń ṣẹ̀ sí ilẹ̀ àní, ọkàn kan kì yóò kù pẹ̀lú rẹ̀ nínú gbogbo àwọn ọmọkùnrin tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀.

13 Bí o bá sì bọ́ sí ìlú kan, gbogbo Ísírẹ́lì yóò mú okùn wá sí ìlú náà, àwa ó sì fà á lọ sí odo, títí a kì yóò fi rí òkúta kékeké kan níbẹ̀.”

14 Ábúsálómù àti gbogbo ọkùnrin Ísírẹ́lì sì wí pé, “Ìmọ̀ Húṣáì ará Áríkì sàn ju ìmọ̀ Áhítófélì lọ! Nítorí Olúwa fẹ́ láti yí ìmọ̀ rere ti Áhítófélì po.” Nítorí kí Olúwa lè mú ibi wá sórí Ábúsálómù.

15 Húṣáì sì wí fún Sádókù àti fún Ábíátarì àwọn àlùfáà pé, “Bàyìí ni Áhítófélì ti bá Ábúsálómù àti àwọn àgbà Ísírẹ́lì dámọ̀ràn: báyìí lèmi sì báa dámọ̀ràn.

16 Nítorí náà yára ránṣẹ́ nísinsin yìí kí o sì sọ fún Dáfídì pé, ‘Má ṣe dúró ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ ijù náà lálẹ́ yìí, ṣùgbọ́n yára rékọjá kí a má báa gbé ọba mì, àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ó ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ.’ ”

17 Jónátanì àti Áhímásì sì dúró ní Énrógélì ọ̀dọ́mọdébìnrin kan sì lọ, ó sì sọ fún wọn, wọ́n sì lọ wọ́n sọ fún Dáfídì ọba nítorí pé kí a má báà rí wọn pé wọ́n wọ ìlú.