27 Fún onínú-funfun ni ìwọ fi ara rẹ hàn ní funfun;àti fún ẹni-wíwọ́ ni ìwọ ó fi ara rẹ hàn ní wíwọ́.
28 Àwọn ènìyàn tí ó wà nínú ìyà ni ìwọ ó sì gbàlà;ṣùgbọ́n ojú rẹ wà lára àwọn agbéraga, láti rẹ̀ wọ́n sílẹ̀.
29 Nítorí ìwọ ni ìmọ́lẹ̀ mi, Olúwa; Olúwa yóò sì sọ òkùnkùn mi di ìmọ́lẹ̀.
30 Bẹ́ẹ̀ ni nítorí nípa rẹ̀ ni èmi ti la àárin ogun kọjá;nípa Ọlọ́run mi èmi ti fo odi kan.
31 “Ọlọ́run yìí, pípé ni ọ̀nà rẹ̀;ọ̀rọ̀ Olúwa ni a ti dán wò.Òun sì niaṣà fún gbogbo àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé e.
32 Nítorí ta ni Ọlọ́run, bí kò ṣe Olúwa?Ta ni àpáta, bí kò ṣe Ọlọ́run wa.
33 Ọlọ́run alágbára ni ó fún mi ní agbára,ó sì sọ ọ̀nà mi di títọ́.