45 Àwọn àlejò wá láti tẹríba fún mi;bí wọ́n bá ti gbúròó mi, wọn á sì gbọ́ tèmi.
46 Àyà yóò pá àwọn àlejò,wọn ó sì fi ìbẹ̀rù sá kúrò níbi kọ́lọ́fín wọn.
47 “Olúwa ń bẹ́; olùbùkún sì ni àpáta mi!Gbígbéga sì ni Ọlọ́run àpáta ìgbàlà mi.
48 Ọlọ́run ni ẹni tí ń gbẹ̀san mi,àti ẹni tí ń rẹ àwọn ènìyàn sílẹ̀ lábẹ́ mi.
49 Àti ẹni tí ó gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀ta mi.Ìwọ sì gbé mi sókè ju àwọn tí ó dìde sí mi lọ;ìwọ sì gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn ọkùnrin oníwà ipá.
50 Nítorí náà èmi ó fi ọpẹ́ fún ọ, Olúwa,láàrin àwọn àjèjì orílẹ̀-èdè: èmi ó sì kọrin sí orúkọ rẹ.
51 Òun ni ilé-ìṣọ́ ìgbàlà fún ọba rẹ̀;ó sì fi àánú hàn fún ẹni-àmì-òróró rẹ̀,fún Dáfídì, àti fún irú-ọmọ rẹ̀ títí láéláé.”