7 Ibínú Olúwa sì ru sí Úsà; Ọlọ́run sì pa á níbẹ̀ nítorí ìṣìṣe rẹ̀; níbẹ̀ ni ó sì kù ní ẹ̀bá àpótí-ẹ̀rí Ọlọ́run.
8 Inú Dáfídì sì bàjẹ́ nítorí tí Olúwa gé Úsà kúrò: ó sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Peresí-Úsà títí ó fi di òní yìí.
9 Dáfídì sì bẹ̀rù Olúwa ní ijọ́ náà, ó sì wí pé, “Àpótí-ẹ̀rí Olúwa yóò ti ṣe tọ̀ mí wá?”
10 Dáfídì kò sì fẹ́ mú àpótí-ẹ̀rí Olúwa sọ́dọ̀ rẹ̀ sí ìlú Dáfídì; ṣùgbọ́n Dáfídì sì mú un yà sí ilé Obedì-Édómù ará Gátì.
11 Àpótí-ẹ̀rí Olúwa sì gbé ní ilé Obedì-Édómù ará Gátì ní oṣù mẹ́ta; Olúwa sì bùkún fún Obedì-Édómù, àti gbogbo ilé rẹ̀.
12 A sì rò fún Dáfídì ọba pé, “Olúwa ti bùkún fún ilé Obedì-Édómù, àti gbogbo èyí tí í ṣe tirẹ̀, nítorí àpótí-ẹ̀rí Ọlọ́run.” Dáfídì sì lọ, ó sì mú àpótí-ẹ̀rí náà gòkè láti ilé Obedì-Édómù wá sí ìlú Dáfídì pẹ̀lú ayọ̀.
13 Ó sì ṣe nígbà tí àwọn ènìyàn tí ó ru àpótí-ẹ̀rí Olúwa bá sì ṣí ẹsẹ̀ mẹ́fà, òun a sì fi màlúù àti ẹran àbọ́pa rúbọ.