1 Èhíhù kan yóò sọ láti ibikùkùté Jéésè,láti ara gbòǹgbò rẹ̀ ni ẹ̀ka kanyóò ti so èso.
2 Ẹ̀mí Olúwa yóò sì bà lé eẹ̀mí ọgbọ́n àti ti òyeẹ̀mí ìmọ̀ràn àti ti agbáraẹ̀mí ìmọ̀ àti ti ìbẹ̀rù Olúwa
3 Òun yóò sì ní inúdídùn nínú ìbẹ̀rù Olúwa.Òun kì yóò ṣe ìdájọ́ pẹ̀lú ohun tí ó fi ojúu rẹ̀ rí,tàbí pẹ̀lú ohun tí ó fi etíi rẹ̀ gbọ́,
4 Ṣùgbọ́n pẹ̀lú òdodo ni yóò ṣe ìdájọ́ àwọn aláìní,pẹ̀lú òtítọ́ ni yóò ṣe ìpinnufún àwọn aláìní ayé.Òun yóò lu ayé pẹ̀lú ọ̀pá tí ó wà ní ẹnu rẹ̀,pẹ̀lú ooru ẹnu rẹ̀ ni yóò pa àwọn ìkà.
5 Òdodo ni yóò jẹ́ ìgbànú rẹ̀àti òtítọ́ ni yóò ṣe ọ̀já yí ẹ̀gbẹ́ẹ rẹ̀ ká.