23 “Èmi yóò yí i padà sí ibùgbé àwọn òwìwíàti sí irà;Èmi yóò fi ọwọ́ ìparun gbá a,”ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
24 Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti búra,“Gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣètò, bẹ́ẹ̀ ni yóò rí,àti bí mo ti pinnu, bẹ́ẹ̀ ni yóò sì dúró.
25 Èmi yóò run Ásíríà ní ilẹ̀ mi,ní àwọn orí òkè mi ni èmi yóò ti rún un mọ́lẹ̀.Àjàgà rẹ̀ ni a ó mú kúrò lọ́rùn àwọn ènìyàn mi,ẹrù u rẹ̀ ni ó mú kúrò ní èjìkáa wọn.”
26 Èyí ni ètò tí a pinnu rẹ̀ fún gbogbo ayé,èyí ni ọwọ́ tí a nà jáde káàkiri gbogbo orílẹ̀ èdè.
27 Nítorí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti pète,ta ni yóò sì ká a lọ́wọ́ kò?Ọwọ́ọ rẹ ti nà jáde, ta ni ó sì le è fà á padà?
28 Ọ̀rọ̀ ìmọ̀ yí wá ní ọdún tí ọba Áhásì kú:
29 Má ṣe yọ̀, gbogbo ẹ̀yin Fílístínì,pé ọ̀pá tí ó lù ọ́ ti dá;láti ibi gbòngbò ejò náà ni pamọ́lẹ̀yóò ti hù jáde,èṣo rẹ̀ yóò sì jẹ́ oró ejò tíí jóni.