1 Ọ̀rọ̀ ìmọ̀ tí ó kan Móábù:A pa Árì run ní Móábù,òru kan kí a paárun!A pa Kárì run ní Móábù,òru kan kí a paárun!
2 Díbónì gòkè lọ sí tẹ́ḿpìlìi rẹ̀,sí àwọn ibi gíga rẹ̀ láti ṣunkún,Móábù pohùnréré lórí Nébónì àti Médíbà.Gbogbo orí ni a fágbogbo irungbọ̀n ni a gé dànù.
3 Wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀ ní ojú òpópónà,ní àwọn òrùlé àti àwọn gbàgede àkójọwọ́n pohùnréré,Wọ́n dọ̀bálẹ̀ pẹ̀lú ẹkún.
4 Hẹ́ṣíbónì àti Élíálè ké ṣóde,ohùn wọn ni a gbọ́ títí fi dé Jáhásì.Nítorí náà ni àwọn ọmọ ogun Móábù ṣe kígbetí ọkàn wọn sì rẹ̀wẹ́sì.