Àìsáyà 17:8-14 BMY

8 Wọn kò ní wo àwọn pẹpẹ mọ́,èyí tí í ṣe iṣẹ́ ọwọ́ọ wọn,wọn kò sì ní kọbi ara sí òpó Áṣérà mọ́tàbí pẹpẹ tùràrí tí ìka ọwọ́ wọn ti ṣe.

9 Ní ọjọ́ náà àwọn ìlú alágbára wọn, tí wọ́n fi sílẹ̀ nítorí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, yóò dàbí ilẹ̀ tí a dà sílẹ̀ kó di ìgbòrò. Gbogbo wọn yóò sì di ahoro.

10 Ẹ ti gbàgbé Ọlọ́run Olùgbàlà yín;ẹ kò sì rántí àpáta náà, àní odi agbára yín.

11 Nítorí náà, bí ẹ tilẹ̀ mú àsàyàn igi tí ẹ sì gbin àjàrà tí ó ti òkèrè wá,bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ tí ẹ kó wọn jáde ẹ mú wọn hú jáde,àti ní òwúrọ̀ tí ẹ gbìn wọ́nẹ mú kí wọ́n rúdí,ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀ ìkóórè kò ní mú nǹkan wání ọjọ́ àrùn àti ìrora tí kò gbóògùn.

12 Kíyèsii, ìrunú àwọn orílẹ̀ èdè—wọ́n ń runú bí ìgbì òkun!Kíyèsii, rògbòdìyàn tí ogunlọ́gọ̀ ènìyànwọ́n bú ramúramù gẹ́gẹ́ bí ariwo odò ńlá!

13 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn ń búramúramù gẹ́gẹ́ bí ìrúmi odò,nígbà tí ó bá wọn wí wọ́n ṣálọ jìnnà réré,a tì wọ́n lọ gẹ́gẹ́ bí ìyàngbò ní orí òkè,àti gẹ́gẹ́ bí ewéko níwájú ìjì líle.

14 Ní ihà, ìpayà òjijì!Kí ó tó di òwúrọ̀, a ò rí wọn mọ́!Èyí ni ìpín àwọn tí ó jí wa lẹ́rù,àti ìpín àwọn tí ó fi ogun kó wa.