1 Kíyèsí i, Olúwa yóò sọ ohungbogbo dòfo ní ilẹ̀ ayéyóò sì pa á runòun yóò pa ojúu rẹ̀ rẹ́yóò sì fọ́n àwọn olùgbé ibẹ̀ káàkiri—
2 bákan náà ni yóò sì rífún àlùfáà àti àwọn ènìyàn,fún ọ̀gá àti ọmọ ọ̀dọ̀,fún ìya-ilé àti ọmọbìnrin,fún olùtà àti olùrà,fún ayáni àti atọrọfún ayánilówó àti onígbésè.
3 Ilé ayé ni a ó sọ di ahoro pátapátaa ó sì jẹ gbogbo rẹ̀ run. Olúwa ni ó ti sọ ọ̀rọ̀ yìí.
4 Ilẹ̀ ayé ti gbẹ ó sì ṣá,ayé ń ṣòjòjò, àárẹ̀ mú un,àwọn ẹni gíga ilẹ̀ ayé wà nínú ìpọ́njú