12 Ìlú ni a ti fi sílẹ̀ ní ahoro,ìlẹ̀kùn rẹ̀ ni a sì ti pa bámú bámú.
13 Bẹ́ẹ̀ ni yóò sì rí ní orí ilẹ̀ ayéàti láàrin àwọn orílẹ̀ èdè pẹ̀lú,gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí a lu igi ólífì,tàbí gẹ́gẹ́ bí i pàǹtí tí ó ṣẹ́kù lẹ́yìntí a kórè èso tán.
14 Wọ́n gbé ohùn wọn ṣókè, wọ́n sì hó fún ayọ̀;láti ìwọ̀ oòrùn ni wọn yóò ti polongoọlá-ńlá Olúwa.
15 Nítorí náà ní ìlà oòrùn ẹ fi ògo fún Olúwa;gbé orúkọ Olúwa ga, àníỌlọ́run Ísírẹ́lì,ní àwọn erékùṣù ti inú òkun,
16 Láti òpin ayé wá ni a ti gbọ́ orin;“Ògo ni fún olódodo n nì.”Ṣùgbọ́n mo wí pé, “mo ṣègbé, mo ṣègbé!”“Ègbé ni fún mi!Alárékérekè dalẹ̀!Pẹ̀lú ìhàlẹ̀ ni àgàbàgebè fi dalẹ̀!”
17 Ìpáyà, isà-òkú, àti ìdẹkùn ń dúró dè ọ́,Ìwọ ènìyàn ilẹ̀ ayé.
18 Ẹnikẹ́ni tí ó bá sá nítorí ariwo ìpayàyóò ṣubú sínú ihò,ẹnikẹ́ni tí ó bá sì yọ́ jáde nínú ihòni ìdẹkùn yóò gbámú.Ibodè ọ̀run ti wà ní sísí sílẹ̀Ìpìlẹ̀ ayé mì tìtì.