6 Nítorí náà, ègún kan ti jẹ ayé run;àwọn ènìyàn rẹ̀ ní láti ru ẹ̀bi wọn.Nítorí náà, àwọn olùgbé ayé ti gbiná dànù,àwọn ẹ̀tàhóró ló sì kù.
7 Wáìnì tuntun ti gbẹ, àjàrà sì ti rọ,gbogbo àwọn alárìíyá sì kérora.
8 Àríyá ti tamborínì ti dákẹ́ariwo àwọn tí ń ṣàjọyọ̀ ti dáwọ́ dúróayọ̀ hápù ti dákẹ́ jẹ́ẹ́.
9 Kò ṣeéṣe fún wọn láti máa mu wáìnì pẹ̀lú orin kíkọ mọ́ọtí líle ti di ìkorò fún àwọn ọ̀mu.
10 Ìlú tí a run ti dahoro,ẹnu ọ̀nà à bá wọlé kọ̀ọ̀kan ni a dí pa.
11 Ní òpópónà ni wọ́n ti ń kígbe fún wáìnìgbogbo ayọ̀ọ wọn ti di ìbànújẹ́,gbogbo àríyá ni a lé kúrò lórí ilẹ̀ ayé.
12 Ìlú ni a ti fi sílẹ̀ ní ahoro,ìlẹ̀kùn rẹ̀ ni a sì ti pa bámú bámú.