14 Ohun tí ọba wí nìyìí: Ẹ má ṣe jẹ́ kí Heṣekáyà tàn yín jẹ. Òun kò le è gbà yín sílẹ̀!
15 Ẹ má ṣe jẹ́ kí Heṣekáyà rọ̀ yín láti gbẹ́kẹ̀lé Olúwa nígbà tí ó sọ pé, ‘Olúwa yóò kúkú gbà wá; a kì yóò fi ìlú lé ọba Ásíríà lọ́wọ́.’
16 “Ẹ má ṣe tẹ́tí sí Heṣekáyà. Ohun tí ọba Áṣíríà wí nìyìí: Ẹ ṣètò àlàáfíà pẹ̀lúù mi kí ẹ sì jáde tọ̀ mí wá. Lẹ́yìn náà ẹnìkọ̀ọ̀kan yín yóò sì jẹ nínú àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni yóò sì mumi nínú kàǹga rẹ̀,
17 títí tí èmi yóò fi mú un yín lọ sí ilẹ̀ kan tí ó dàbí i ti yín, ilẹ̀ tí ó ní irúgbìn oníhóró àti wáìnì tuntun, ilẹ̀ tí ó ní àkàrà àti ọgbà àjàrà.
18 “Ẹ má ṣe jẹ́ kí Heṣekáyà sì yín lọ́nà nígbà tí ó sọ wí pé, ‘Olúwa yóò gbà wá.’ Ǹjẹ́ ọlọ́run orílẹ̀ èdè kan ha ti gbà á kúrò lọ́wọ́ ọba Áṣíríà bí?
19 Níbo ni àwọn òrìṣà Hámátì àti Ápádì ha wà? Níbo ni àwọn òrìṣà Ṣépáfírámù ha wà? Ǹjẹ́ wọn ti já Ṣamáríà gbà kúrò lọ́wọ́ mi bí?
20 Èwo nínú àwọn òrìṣà orílẹ̀ èdè wọ̀nyí ló ha ti dáàbò bo ilẹ̀ẹ rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ mi? Báwo ni Olúwa ṣe wá le gba Jérúsálẹ́mù kúrò lọ́wọ́ mi?”