3 Tẹ́tí sílẹ̀ kí o sì wá sọ́dọ̀ migbọ́ tèmi, kí ọkàn rẹ lè wà láàyè.Èmi yóò dá májẹ̀mú ayérayé pẹ̀lúù rẹ,ìfẹ́ Òtítọ́ tí mo ṣèlérí fún Dáfídì.
4 Kíyèsí i, mo ti fi òun ṣe ẹlẹ́rìí fún àwọn ènìyàn,olórí àti apàṣẹ fún àwọn ènìyàn.
5 Lótìítọ́ ìwọ yóò ké sí àwọn orílẹ̀ èdè tí ìwọ kò mọ̀àti orílẹ̀ èdè tí ìwọ kò mọ̀ ni yóò sáré tọ̀ ọ́ wá,Nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹẸni Mímọ́ Ísírẹ́lìnítorí pé ó ti fi ohun dídára dá ọ lọ́lá.”
6 Ẹ wá Olúwa nígbà tí ẹ lè rí i;ẹ pè é nígbà tí ó wà nítòsí.
7 Jẹ́ kí ìkà kí ó kọ ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀àti ènìyàn búburú èrò rẹ̀.Jẹ́ kí ó yípadà sí Olúwa, Òun yóò sì ṣàánú fún un,àti sí Ọlọ́run wa, nítorí Òun yóò sì dáríjìn ín jọjọ.
8 “Nítorí èrò mi kì í ṣe èrò yín,tàbí ọ̀nà yín a há máa ṣe ọ̀nà mi,?”ni Olúwa wí.
9 “Gẹ́gẹ́ bí ọ̀run ti ga ju ayé lọ,bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi ga ju ọ̀nà yín lọàti èrò mi ju èrò yín lọ.