Dáníẹ́lì 12:6-12 BMY

6 Ọ̀kan lára wọn sọ fún ọkùnrin tí ó wọ aṣọ àlà, ẹni tí ó wà lórí omi odò pé, “Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó kí àwọn nǹkan ìyanu wọ̀nyí tó wá sí ìmúṣẹ?”

7 Ọkùnrin tí ó wọ aṣọ àlà, ẹni tí ó wà lórí omi odò, gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti ọwọ́ òsì rẹ̀, mo gbọ́ tí ó fi ẹni tí ó wà títí láé búra, ó sọ wí pé, “Yóò ṣe ní àkókò kan, àkókò méjì àti ààbọ̀. Nígbà tí agbára àwọn ẹni mímọ́ yóò ti fọ́ tán pátapáta, gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò sì parí.”

8 Èmi gbọ́, ṣùgbọ́n kò yé mi. Nígbà náà ni mo bèèrè pé, “Olúwa mi, kí ni yóò jẹ́ àbábọ̀ àwọn nǹkan wọ̀nyí?”

9 Ó sì dáhùn pé, “Má a lọ ní ọ̀nà rẹ, Dáníẹ́lì nítorí tí a ti pa ọ̀rọ̀ náà dé, a sì ti fi èdìdì dìí di ìgbà ìkẹyìn.

10 Ọ̀pọ́lọpọ̀ ni a ó fọ̀ mọ́, wọn yóò wà láì lábàwọ́n, a ó sì tún wọn ṣe, ṣùgbọ́n àwọn ẹni búburú yóò máa ṣe búburú lọ, kò sí ẹni búrurú tí òye yóò yé ṣùgbọ́n òye yóò yé àwọn ọlọ́gbọ́n.

11 “Láti àkókò tí a ó mú ẹbọ ojoojúmọ́ kúrò, tí a ó sì gbé ìríra tí ó ń fa ìsọdahoro kalẹ̀ yóò sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún àti igba lé àádọ́rùn-ún ọjọ́ (1,290).

12 Ìbùkún ni fún ẹni tí ó dúró tì ọ́ àti tí ó sì di òpin ẹgbẹ̀rún àti ọ̀ọ́dúnrún lé àrùndínlógójì ọjọ́. (1,335)