7 Ṣùgbọ́n ojú u yín gan an ni ó rí gbogbo nǹkan ńlá wọ̀nyí tí Olúwa ti ṣe.
8 Nítorí náà, ẹ kíyèsí gbogbo àṣẹ tí mo ń fún un yín lónìí, kí ẹ ba à lè lágbára àti lọ, kí ẹ sì gba ilẹ̀ náà tí ẹ ó la Jọ́dánì kọjá lọ.
9 Kí ẹ ba à lè pẹ́ ní orí ilẹ̀ tí Olúwa ti búra fún àwọn baba ńlá a yín, láti fún àwọn àti àwọn ọmọ wọn: ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti oyin.
10 Ilẹ̀ tí ẹ̀ ń wọ̀ lọ láti gbà kò rí bí ilẹ̀ Éjíbítì, níbi tí ẹ ti wá, níbi tó jẹ́ wí pé ẹṣẹ̀ yín ni ẹ fi ń rìn lọ bominrin irúgbìn tí ẹ gbìn bí oko ẹ̀fọ́.
11 Ṣùgbọ́n ilẹ̀ tí ẹ ó la Jọ́dánì kọjá láti gbà, jẹ́ ilẹ̀ olókè àti pẹ̀tẹ́lẹ̀ tí òjò ń rọ̀ sí latọ̀run.
12 Ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run yín ń mójútó ni, ojú Olúwa Ọlọ́run yín sì ń fi ìgbà gbogbo wà lórí rẹ̀, láti ìbẹ̀rẹ̀ ọdún dé òpin ọdún.
13 Nítorí náà, bí ẹ bá gbọ́ràn sí àṣẹ tí mo fún un yín lónìí tọkàntọkàn: tí ẹ fẹ́ràn Olúwa Ọlọ́run yín, tí ẹ sì sìn ín, pẹ̀lú gbogbo àyà yín àti gbogbo ọkàn yín: