8 Ṣùgbọ́n ẹ lawọ́ kí ẹ sì fi tọkàntọkàn yá wọn ní ohun tí wọ́n nílò.
9 Ẹ sọ́ra kí èrò búburú kan má ṣe sí nínú àyà rẹ wí pé, “Ọdún kéje tí í ṣe ọdún ìyọ̀ǹda gbésè ti súnmọ́” nípa bẹ́ẹ̀, ojú rẹ a sì burú sí arákùnrin rẹ talákà, tí ìwọ kò sì fun ní nǹkan, o kò sì fun ní nǹkan kan. Òun a si kígbe pe olúwa nitori rẹ, a si di ẹ̀ṣẹ̀ fún ọ.
10 Fún un tọkàntọkàn, láì sí ìkùnsínú, nítorí èyí, Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò bùkun fún ọ nínú iṣẹ́ ọwọ́ rẹ, àti gbogbo ìdáwọ́lé rẹ.
11 A kò lè fẹ́ tálákà kù ní ilẹ̀ náà ní ìgbà gbogbo, mo pàṣẹ fún un yín láti lawọ́ sí àwọn arákùnrin yín, sí àwọn talákà àti sí àwọn aláìní, ní ilẹ̀ ẹ yín.
12 Bí Hébérù ara yín kan, yálà ọkùnrin tàbí obìnrin bá ta ara rẹ̀ fún ọ, tí ó sì sìn ọ́ fún ọdún mẹ́fà. Ní ọdún kéje, jẹ́ kí ó di òmìnira.
13 Nígbà tí ó bá dá a sílẹ̀ má ṣe jẹ́ kí ó lọ lọ́wọ́ òfo.
14 Fi tọkàntọkàn fún un láti inú agbo ewúrẹ́ rẹ, ilẹ̀ ìpakà rẹ, àti ibi ìfúntí rẹ. Fún un gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti bùkún fún ọ tó.