1 “Ìwọ kò gbọdọ̀ tan ìròyìn èké kalẹ̀: Ìwọ kò gbọdọ̀ ran ènìyàn búburu lọ́wọ́ láti jẹ́rìí èké.
2 “Ìwọ kò gbọdọ̀ tẹ̀lé ọ̀pọ̀ ènìyàn láti se aburú. Nígbà tí ìwọ bá jẹ́rìí sí ẹjọ́, ìwọ kò gbọdọ̀ yí ìdájọ́ po nípa gbígbé lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ènìyàn.
3 Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúṣáájú sí talákà nínú ẹjọ́ rẹ̀.
4 “Bí ìwọ bá se alábàápàdé akọ màlúù tàbí akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ọ̀ta rẹ tí ó sinà lọ, rí i dájú pé o mú un padà wá fún un.
5 Bí ìwọ bá rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ẹnìkan tí ó koríra rẹ tí ẹrù subú lé lórí, má ṣe fi í sílẹ̀ bẹ́ẹ̀; rí i dájú pé o ran án lọ́wọ́ nípa rẹ.
6 “Ìwọ kò gbọdọ̀ du aláìní ní ìdájọ́ òdodo.