6 Mósè bu ìlàjì ẹ̀jẹ̀ ẹran sínú abọ́, ó sì fi ìlàjì tókù wọn ara pẹpẹ.
7 Nígbà náà ni ó sì mú ìwé májẹ̀mú, ó sì kà á sí àwọn ènìyàn. Wọ́n dáhùn pé, “Àwa yóò ṣe gbogbo ohun tí Olúwa wí: Àwa yóò sì gbọ́ràn.”
8 Nígbà náà ni Mósè gbé ẹ̀jẹ̀, ó sì wọn sí àwọn ènìyàn náà lára pé, “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú tí Ọlọ́run ti ṣe pẹ̀lú yín ni ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí.”
9 Mósè àti Árónì, Nádábù àti Ábíhù àti àádọ́rin àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì gòkè lọ.
10 Wọ́n sì rí Ọlọ́run Ísírẹ́lì. Ní abẹ́ ẹṣẹ̀ rẹ̀ ni ohun kan bí i pèpéle ti a fi òkúta sáfírè ṣe wà. Èyí ti ó mọ́ niṣínniṣín bí àwọ̀ sánmọ̀ fúnraarẹ̀.
11 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì wọ̀nyí; wọ́n ri Ọlọ́run, wọ́n jẹ, wọ́n sì mu.
12 Olúwa sì sọ fún Mósè pé, “Gòkè wá sí ọ̀dọ̀ mi, kí o sì dúró níhín-ín. Èmi yóò sì fún ọ ní òkúta ìkọ̀wé pẹ̀lú òfin àti ìlànà tí mo ti kọ sílẹ̀ fún ìtọ́sọ́nà wọn.”