19 Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò máa wẹ ọwọ́ àti ẹṣẹ̀ wọn pẹ̀lú omi tí ó wà nínú rẹ̀.
20 Nígbàkígbà tí wọ́n bá wọ inú àgọ́ àjọ, wọ́n yóò wẹ̀ pẹ̀lú omi nítorí kí wọ́n má ba à kú. Bákan náà, nígbà tí wọ́n bá sún mọ́ ibi pẹpẹ láti ṣe ìṣìn, láti mú ẹbọ ti a fi iná sun wá fún Olúwa,
21 wọn yóò sì wẹ ọwọ́ wọn àti ẹsẹ̀ wọn, nítorí kí wọn máa ba à kú. Èyí ni yóò jẹ́ ìlànà títí láé fún Árónì àti irú àwọn ọmọ rẹ̀ fún ìrandìran wọn.”
22 Olúwa sọ fún Mósè pé,
23 Ìwọ yóò mú ààyò tùràrí olóòórùn sí ọ̀dọ̀ rẹ; ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta sékélì (kílógíráámù mẹ́fà) tí òjíá sísàn, ìdajì bí ó bá yẹ àádọ́tàlérúgba (250) sékélì tí kínámónì dídùn, àti kane dídùn àádọ́tàlérúgba (250) sékélì,
24 kaṣia ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) sékélì-gbogbo rẹ̀ ní ìlànà sékélì ibi mímọ́ àti hínì òrórò ólífì kan (lítà mẹ́rin).
25 Ṣe ìwọ̀nyí ní òróró mímọ́ ìkunra, tí a pò pọ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣe-òórùn dídùn tì í ṣe, Yóò jẹ òróró mímọ́ ìtasórí.