25 “Má ṣe ta ẹ̀jẹ̀ ẹbọ sí mi pẹ̀lú ohunkóhun tí ó bá ní ìwúkàrà, kí o má sì se jẹ́ kí ẹbọ ìrékọjá kù títí di òwúrọ̀.
26 “Mú èyí tí ó dára nínú àkọ́so èso ilẹ̀ rẹ wá sí ilé Olúwa Ọlọ́run rẹ.“Má ṣe ṣe ọmọ ewúrẹ́ nínú wàrà ìyá rẹ̀.”
27 Olúwa sì wí fún Mósè pé, “Kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sílẹ̀, nítorí nípa àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni èmi bá ìwọ àti Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú.”
28 Mósè wà níbẹ̀ pẹ̀lú Olúwa fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru (40) láì jẹ oúnjẹ tàbí mu omi. Ó sì kọ ọ̀rọ̀ májẹ̀mú náà òfin mẹ́wàá sára wàláà.
29 Nígbà tí Mósè sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè Ṣínáì pẹ̀lú wàláà ẹ̀rí méjì ní ọwọ́ rẹ̀, òun kò mọ̀ pé ojú òun ń dán nítorí ó bá Olúwa sọ̀rọ̀.
30 Nígbà tí Árónì àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí Mósè, ojú rẹ̀ ń dán, ẹ̀rù sì ń bà wọ́n láti sún mọ́ ọn.
31 Ṣùgbọ́n Mósè pè wọn; Árónì àti gbogbo àwọn olórí àjọ padà wá bá a, ó sì bá wọn sọ̀rọ̀.