1 Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé:
2 “Ọmọ ènìyàn, pohùnréré ẹkún fún Tírè.
3 Sọ fún Tírè, tí a tẹ̀dó sí ẹnu bodè òkun, oníṣòwò àwọn orílẹ̀-èdè fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ erékùṣù. ‘Èyí yìí ní Olúwa Ọlọ́run wí:“ ‘Ìwọ Tírè wí pé“Ẹwá mi pé.”
4 Ààlà rẹ wà ní àárin òkun;àwọn ọ̀mọ̀lé rẹ ti mú ẹwà rẹ pé.