20 Ẹja inú òkun, àwọn ẹyẹ òfuurufú, àwọn ẹranko igbó, àti gbogbo ẹ̀dá tí ó ń rìn lórí ilẹ̀ yóò wárìrì fún ìfarahàn mi. A óò yí òkè gíga po, àwọn bèbè òkúta ni àwa yóò fọ́ sí wẹ́wẹ́, gbogbo ògiri ni yóò wó palẹ̀.
21 Èmi yóò fa idà yọ ni ìlòdì sí Gógì ní orí gbogbo àwọn òkè gíga mi ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. Idà gbogbo ènìyàn yóò lòdì sí arákùnrin rẹ̀.
22 Èmi yóò gbé ìdájọ́ mi jáde lórí rẹ̀ pẹ̀lú ìyọnu àti ìtàjẹ̀sílẹ̀; Èmi yóò dá àgbàrá òjò, òkúta yìnyín àti imí ọjọ́ tí ń jó lé e lórí àti lórí ọ̀wọ́ ogun àti lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè pẹ̀lú rẹ̀.
23 Nítorí náà, Èmi yóò fi títóbi mi àti ìjẹ́-mímọ́ mi hàn, Èmi yóò sì fi ara mi hàn ní ojú ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè. Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.’