Ísíkẹ́lì 6:6-12 BMY

6 Gbogbo ibi tí ẹ ń gbé àti àwọn ibi gíga yín ni yóò di píparun, gbogbo pẹpẹ yín ni yóò di ahoro, àwọn òrìṣà yín yóò di fífọ́ túútúú, àwọn pẹpẹ tùràrí yín ni a ó gé lulẹ̀, gbogbo iṣẹ́ yín yóò parẹ́.

7 Àwọn ènìyàn yín yóò ṣubú láàrin yín, ẹ ó sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.

8 “ ‘Ṣùgbọ́n n ó dá àwọn kan sí nítorí pé díẹ̀ nínú yín ni yóò bọ́ lọ́wọ́ idà, nígbà tí a bá fọ́n yín ká sí gbogbo ilẹ̀ àti orílẹ̀ èdè.

9 Àwọn ti ó bọ́ nínú yin yóò sì ránti mi láàrin àwọn orílẹ́-èdè níbi tí wọn o dì wọ́n ní ìgbèkùn lọ, nítorí ti mo ti tọ́ ọkàn àgbèrè wọn ti o ti lọ kúrò, lọ́dọ̀ mi àti pẹ̀lú ojú wọn, ti n sàgbérè lọ sọ́dọ̀ òrìsà wọn, wọn o si sú ara wọn nítorí ìwà ibi ti wọn ti hù nínú gbogbo ìríra wọn.

10 Wọn yóò sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa; àti pé kì í ṣe lásán ni mo ń lérí pé n ó mú ìdààmú bá wọn.

11 “ ‘Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run wí: Pàtẹ́wọ́ kí o tún fẹsẹ̀ janlẹ̀, kí o wá kígbe síta pé, “Ó ṣe!” ilé Ísírẹ́lì yóò ṣubú nípa idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn nítorí gbogbo ìwà ìríra búburú tí wọ́n hù. Wọn yóò ṣubú nípa idà àti ìyàn.

12 Ẹni tó wà lókèèrè yóò kú pẹ̀lú àjàkálẹ̀-àrùn, àti ẹni tó wà nítòsí yóò ṣubú pẹ̀lú idà, ìyàn ni yóò pa ẹni tó bá ṣẹ́kù sílẹ̀. Báyìí ni n ó ṣe mú ìbínú gbígbóná mi wá sórí wọn.