Jeremáyà 25:9-15 BMY

9 Èmi yóò pe gbogbo àwọn ènìyàn àríwá, àti ìránṣẹ́ mi Nebukadinésárì Ọba Bábílónì,” ni Olúwa wí. “Èmi yóò sì mú wọn dìde lòdì sí ilẹ̀ náà àti àwọn olùgbé rẹ̀ àti sí gbogbo orílẹ̀ èdè àyíká rẹ̀. Èmi yóò pa wọ́n run pátapáta, Èmi yóò sọ wọ́n di nǹkan ẹ̀rù àti yẹ̀yẹ́ àti ìparun ayérayé.

10 Èmi yóò sì mú ìró ayọ̀ àti inú dídùn kúrò lọ́dọ̀ wọn; ohùn ìyàwó àti ọkọ ìyàwó, ìró ọlọ òkúta àti ìmọ́lẹ̀ fìtílà.

11 Gbogbo orílẹ̀ èdè yìí yóò sì di ahoro, orílẹ̀ èdè yìí yóò sì sìn ní Bábílónì ní àádọ́rin ọdún.

12 “Ṣùgbọ́n, nígbà tí àádọ́rin ọdún náà bá pé; Èmi yóò fi ìyà jẹ Ọba Bábílónì àti orílẹ̀ èdè rẹ, ilẹ̀ àwọn ará Bábílónì nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn,” ni Olúwa wí; “bẹ́ẹ̀ ni Èmi yóò sọ ọ́ di ahoro títí láé.

13 Èmi yóò sì mú gbogbo ohun tí mo ti sọ wọ̀nyí wá sórí ilẹ̀ náà, gbogbo ohun tí a ti sọ ani gbogbo èyí tí a ti kọ sínú ìwé yìí, èyí tí Jeremáyà ti sọ tẹ́lẹ̀ sí gbogbo orílẹ̀-èdè.

14 Àwọn fúnra wọn yóò sì sin orílẹ̀ èdè púpọ̀ àti àwọn Ọba ńlá. Èmi yóò sì sán fún oníkálukú gẹ́gẹ́ bí ìṣe àti iṣẹ́ ọwọ́ wọn.”

15 Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí fún mi: “Gba aago yìí ní ọwọ́ mí tí ó kún fún ọtí wáìnì ìbínú mi, kí o sì mú gbogbo orílẹ̀ èdè ti mo rán ọ sí mu ún.