11 “Èmi yóò sì sọ Jérúsálẹ́mù di òkìtìàlàpà àti ìhò àwọn ìkokò.Èmi ó sì sọ ìlú Júdà di ahorotí ẹníkẹ́ní kò sì ní le è gbé.”
12 Ta ni ẹni náà tí ó ní ọgbọ́n láti mòye nǹkan wọ̀nyí? Ta ni Olúwa ti sọ èyí fún, tí ó sì lè ṣàlàyé rẹ̀? È é ṣe tí ilẹ̀ náà fi ṣègbé bí ihà, tí ẹnìkankan kò sì le là á kọjá?
13 Olúwa sì wí pé, nítorí pé wọ́n ti kọ òfin mi sílẹ̀, èyí tí mo gbé kalẹ̀ níwájú wọn, wọn ṣe àìgbọ́ràn sí wọn, wọn kò sì rìn nínú òfin mi.
14 Dípò èyí, wọ́n ti tẹ̀lé agídí ọkàn wọn, wọ́n ti tẹ̀lé Báálì gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wọn ṣe kọ́ wọn.
15 Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa Àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, “Wò ó, Èmi yóò mú kí àwọn ènìyàn wọ̀nyí jẹ oúnjẹ kíkorò àti láti mu omi májèlé.
16 Èmi yóò sì tú wọn ká láàrin àwọn orílẹ̀ èdè, nínú èyí tí àwọn tàbí àwọn baba wọn kò mọ̀. Èmi yóò sì lépa wọn pẹ̀lú idà títí èmi yóò fi pa wọ́n run.”
17 Èyí sì ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Àwọn ọmọ ogun wí:“Ṣáà wò ó nísisìnyìí! Ké sí obìnrin ọlọ́fà nì kí ó wá;sì ránsẹ́ pe àwọn tí ó mòye nínú wọn.