17 Èyí sì ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Àwọn ọmọ ogun wí:“Ṣáà wò ó nísisìnyìí! Ké sí obìnrin ọlọ́fà nì kí ó wá;sì ránsẹ́ pe àwọn tí ó mòye nínú wọn.
18 Jẹ́ kí wọn wá kíákíá,kí wọn wá pohùnréré ẹkúnlé wa lórí títí ojú wa yóòfi ṣàn fún omijé tí omi yóò sì máa ṣàn àwọn ìpéǹpéjú wa
19 A gbọ́ igbe ìpohùnréréẹkún ní Síónì:‘Àwa ti ṣègbé tó!A gbọdọ̀ fi ilẹ̀ wa sílẹ̀,nítorí pé àwọn ilé wa ti parun.’ ”
20 Nísínsìnyìí, ẹ̀yin obìnrin ẹ gbọ́ọ̀rọ̀ Olúwa. Sí etí yín síọ̀rọ̀ ẹnu rẹ. Kọ́ àwọn ọmọbìnrinyín ní ìpohùnréréẹkún, kí ẹ sì kọ́ ara yín ní arò.
21 Ikú ti gba ojú fèrèsé wa wọléó sì ti wọ odi alágbára waó ti ké àwọn ọmọ kúrò níàdúgbò àti àwọn ọ̀dọ́mọ́kùnrinkúrò ní gbọ̀ngàn ìta gbangba.
22 Sọ pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí:“ ‘Òkú àwọn ènìyàn yóò ṣubúbí ààtàn ní oko gbangbaàti bí ìbùkúnwọ́ lẹ́yìn olùkórèláìsí ẹnìkankan láti kó wọn jọ.’ ”
23 Èyí ni ohun tí Olúwa wí:“Má ṣe jẹ́ kí ọlọgbọ́n yangànnítorí ọgbọ́n rẹ̀, tàbí alágbáranítorí rẹ̀, tàbí ọlọ́rọ̀nítorí ọrọ̀ rẹ̀.